Saamu 138
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ti Dafidi
138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.