Saamu 106
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
106 (A)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
3 Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.
4 Rántí mi, Olúwa,
Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
5 Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
6 Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
a sì ti hùwà búburú
7 Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,
iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,
wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa
8 Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ
láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀
9 O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ;
o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù
10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn
láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n
11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni
kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́
wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ
14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò
15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀
18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20 Wọ́n pa ògo wọn dà
sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22 Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa
23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.
24 Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà
wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
25 Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn
wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
26 Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
27 Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè
láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,
wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà
29 Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe
àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
30 Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,
àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán
31 A sì ka èyí sí òdodo fún un àti
fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
32 Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,
ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
33 Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn run
gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn,
35 Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn
36 Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn
tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
37 Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ
àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.
38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn
ọmọbìnrin wọn.
Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀
39 Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,
wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
ó mú wọn rí àánú.
47 (B)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
48 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.
Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.