Romu 3:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́
21 (A)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì;
Read full chapter
Galatia 3:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 (A)Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.”
Read full chapter
Filipi 3:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́;
Read full chapter
Heberu 10:38
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
38 Ṣùgbọ́n,
“Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́.
Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn,
ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”
Habakuku 2:4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 (A)“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga;
Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.