Nahumu 2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìṣubú Ninefe
2 Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe
pa ilé ìṣọ́ mọ́,
ṣọ́ ọ̀nà náà
di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le,
múra gírí.
2 Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò
gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run,
tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́.
3 Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa;
àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó.
Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná
ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán;
igi firi ni a ó sì mì tìtì.
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,
wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro.
Wọn sì dàbí ètùfù iná;
tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.
5 Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;
síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;
wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀,
a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
6 A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,
a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.
7 A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀
ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ.
A ó sì mú un gòkè wá
àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà,
wọn a sì máa lu àyà wọn.
8 Ninefe dàbí adágún omi,
tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ.
“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,
ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
9 “Ẹ kó ìkógun fàdákà!
Ẹ kó ìkógun wúrà!
Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,
àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”
10 Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:
ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn,
ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́
àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.
11 Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà
àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,
níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn,
àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù
12 Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀,
ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀,
Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀
àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.
13 “Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín,
idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run.
Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé
Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ
ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.