Matiu 4:23-25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jesu ṣe ìwòsàn
23 (A)Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24 Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Read full chapter
Luku 4:44
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
44 (A)Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.