Add parallel Print Page Options

26 (A)Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”

27 Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀. 28 Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

Read full chapter