Matiu 21:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,
“Hosana fún ọmọ Dafidi!”
“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”
“Hosana ní ibi gíga jùlọ!”
Matiu 23:39
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
39 Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”
Read full chapter
Marku 11:9-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,
“Hosana!”
“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”
10 “Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!”
“Hosana lókè ọ̀run!”
Luku 13:35
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
35 (A)Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”
Read full chapter
Luku 19:38
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
38 (A)Wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
Johanu 12:13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 (A)Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,
“Hosana!”
“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
“Olùbùkún ni ọba Israẹli!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.