Marku 9:38-40
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
38 (A)Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Johanu sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwa rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú wa.”
39 Jesu sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi. 40 Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa.
Read full chapter
Luku 11:23
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
23 (A)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi: ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.