Marku 10:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìkọ̀sílẹ̀
10 (A)(B) Nígbà náà, Jesu kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ẹkùn Judea níhà òkè odò Jordani. Àwọn ènìyàn sì tún tọ̀ ọ́ wá, bí i ìṣe rẹ̀, ó sì kọ́ wọn.
Read full chapter
Luku 17:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá
11 (A)Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili.
Read full chapter
Johanu 4:40-42
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
42 (A)Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.