Luku 12:33-34
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
33 (A)Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. 34 Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.
Read full chapter
Marku 10:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 (A)Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Read full chapter
1 Timotiu 6:17-19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
17 Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò; 18 Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; 19 kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.
Read full chapter
Jakọbu 5:1-3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìkìlọ̀ fún àwọn aninilára ọlọ́rọ̀
5 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. 2 Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. 3 Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.