Jobu 12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìdáhùn Jobu
12 Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,
ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!
3 Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin:
èmi kò kéré sí i yín:
àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?
4 “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn:
à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà,
gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.
6 Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù;
àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,
àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.
7 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,
àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.
8 Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,
àwọn ẹja inú Òkun yóò sì sọ fún ọ.
9 Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan
wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?
10 Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà,
Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.
11 Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí
tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?
12 Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,
àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.
13 “Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára:
Òun ló ni ìmọ̀ àti òye.
14 Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́;
Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.
15 Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ;
Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.
16 Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;
Ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.
17 Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò,
A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.
18 Ó tú ìdè ọba,
Ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.
19 Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò,
Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.
20 Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò,
Ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.
21 Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá,
Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.
22 Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá,
Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.
23 Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;
Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.
24 Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé,
A sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.
25 Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀,
Òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.