Isaiah 2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Òkè Olúwa
2 Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu:
2 (A)Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́
òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀
gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ,
gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.
3 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
4 Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,
wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,
bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
5 Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,
ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.
Ọjọ́ Olúwa
6 Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
ìwọ ilé Jakọbu.
Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,
wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,
wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.
7 Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
8 Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,
wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
9 Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
má ṣe dáríjì wọ́n.
10 Wọ inú àpáta lọ,
fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
kúrò nínú ìpayà Olúwa,
àti ògo ọláńlá rẹ̀!
11 Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀
a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,
Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́
fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga
nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),
13 nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó
àti gbogbo óákù Baṣani,
14 nítorí gbogbo òkè gíga ńláńlá
àti àwọn òkè kéékèèkéé,
15 fún ilé ìṣọ́ gíga gíga
àti àwọn odi ìdáàbòbò,
16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò
àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba
a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀,
Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.
19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta
àti sínú ihò ilẹ̀
kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa
àti ògo ọláńlá rẹ̀,
nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ
àwọn ère fàdákà àti ère wúrà
tí wọ́n ti yá fún bíbọ
sí èkúté àti àwọn àdán,
21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta
àti sínú ihò pàlàpálá àpáta
kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa
àti ògo ọláńlá rẹ̀,
nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
22 Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́,
èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀.
Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.