Esteri 9:23-25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
23 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Mordekai ti kọ̀wé sí wọn. 24 Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnrarẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.