Add parallel Print Page Options

Àwọn Júù yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kórìíra wọn. Àwọn Júù péjọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojúkọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tókù ń bẹ̀rù u wọn.

Read full chapter