Esteri 10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Títóbi Mordekai
10 Ọba Ahaswerusi sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù Òkun 2 Àti gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Mordekai ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Media àti ti Persia? 3 Mordekai ará Júù ni ó jẹ́ igbákejì ọba Ahaswerusi, ó tóbi láàrín àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìre àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.