Esekiẹli 40
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Agbègbè tẹmpili tuntun
40 (A)Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹrìnlá lẹ́yìn Ìṣubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ Olúwa ń bẹ̀ lára mi, òun sì mú mi lọ síbẹ̀. 2 (B)Nínú ìran Ọlọ́run, ó mú mí lọ sí ilẹ̀ Israẹli, ó sì gbé mi lọ sí orí òkè gíga fíofío. Ní ẹ̀gbẹ́ gúúsù ọ̀pọ̀ ilé tó wà níbẹ̀ dàbí ìlú ńlá. 3 (C)Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí baba; ó dúró ni ẹnu-ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. 4 Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì fi ara balẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fihàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síhìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Israẹli.”
Ibi àbájáde tí apá ilà oòrùn àgbàlá ojúde
5 Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mí mọ̀ po. Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìlàsí mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà. Ó wọn ògiri náà; ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni nínípọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga.
6 Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu-ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà-oòrùn. Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu-ọ̀nà ilé; ó jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn. 7 Yàrá kéékèèkéé sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọ̀pá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárín yàrá kéékèèkéé náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Ìloro ẹnu-ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn.
8 Lẹ́yìn náà, ó wọ̀n ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà: 9 Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọn. Ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà kọjú sí tẹmpili.
10 Ní ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ni àwọn yàrá kéékèèkéé mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n. 11 Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu-ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá. 12 Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèkéé kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèkéé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. 13 Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu-ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèkéé kan títí dé òkè ìdojúkọ ọ̀kan; jíjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó ṣí sílẹ̀ sí ìdojúkọ ọ̀kan. 14 Ó sí ṣe àtẹ́rígbà ọlọ́gọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àní títí dé àtẹ́rígbà ògiri àgbàlá, yí ẹnu-ọ̀nà ká. 15 Láti iwájú ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèkéé náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu-ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 16 Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká; Àwọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé àti láti fèrèsé dé òrùlé.
Àgbàlá ojúde
17 Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà, 18 O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu-ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígùn rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀. 19 Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnnà rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu-ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti tí àríwá.
Ẹnu ọnà àríwá
20 Lẹ́yìn náà, ó wọn gígùn àti ibú ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ àríwá, à bá wọ àgbàlá. 21 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu-ọ̀nà àkọ́kọ́. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ìbú. 22 Ojú ihò rẹ̀, àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí í ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà-oòrùn. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà òdìkejì wọn. 23 Ẹnu-ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni ìdojúkọ ẹnu-ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà-oòrùn. Ó wọ́n láti ẹnu-ọ̀nà sí ìdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
Àbájáde sí ìhà gúúsù
24 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúúsù, mo sì rí ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ gúúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù. 25 Ẹnu-ọ̀nà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 26 Àtẹ̀gùn méje ní ń bẹ láti bá gun òkè rẹ̀, àti àwọn ìloro rẹ̀ sì ń bẹ níwájú wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. 27 Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu-ọ̀nà yìí sí ẹnu-ọ̀nà ìta ni ìhà gúúsù; o jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
Àbáwọlé si àgbàlá ti inú
28 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu-ọ̀nà gúúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu-ọ̀nà gúúsù; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 29 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo 30 (Àwọn àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n ni ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jíjìn). 31 Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i.
32 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn ẹnu-ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 33 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 34 Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀.
35 Gẹ́gẹ́ bí àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ ṣe rí. Àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, ó sì ní àwọn ihò yí i po. O jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 36 Àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àwọn ògiri òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká: gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n. 37 Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó so mọ́ ọn lókè.
Àwọn yàrá fún ṣíṣètò ìrúbọ
38 Yàrá kan pẹ̀lú ìlẹ̀kùn wà ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹnu-ọ̀nà inú, níbi tí wọn tí ń fọ àwọn ẹbọ sísun. 39 Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ẹnu-ọ̀nà ni tẹmpili méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, lórí èyí tí a ti ń pa ọrẹ ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 40 Ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ìta àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà tí ẹnu-ọ̀nà, tí ó súnmọ́ àwọn àtẹ̀gùn ní àbáwọlé tí ẹnu-ọ̀nà àríwá ni tẹmpili méjì wà, ní ẹ̀gbẹ́ kejì tí àtẹ̀gùn ní tẹmpili méjì wà. 41 Nítorí náà, tẹmpili mẹ́rin ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan ẹnu-ọ̀nà, mẹ́rin sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì tẹmpili, mẹ́jọ ni gbogbo rẹ̀ lórí èyí ni a ti ń pa ohun ìrúbọ. 42 Tẹmpili mẹ́rin tí à fi òkúta ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ sì tún wà fún ẹbọ sísun, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ni gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ kan ni gíga. Ní orí rẹ̀ ni a kó àwọn ohun èlò fún pípa, ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ìrúbọ tí ó kù sí. 43 Ìlọ́po méjì ohun èlò bí àmúga tí o ní ìwọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìbú ọwọ́ ní gígùn, ni a so mọ́ ara ògiri yíká. Àwọn tẹmpili náà wa fún ẹran ohun ìrúbọ.
Àwọn yàrá fún àwọn àlùfáà
44 Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹmpili. 45 Ó sì wí fún mi pé, “yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà. 46 Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sadoku nínú àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.”
47 Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà.
Tẹmpili náà
48 Ó mú mi lọ sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tẹmpili, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà; wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀. Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ìbú ní ẹ̀gbẹ́ ògiri méjèèjì. 49 Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ìgbọ̀nwọ́ méjìlá láti iwájú dé ẹ̀yìn. Láti ara àtẹ̀gùn ní a ti ń dé ibẹ̀ àwọn òpó sì wà ni ẹ̀gbẹ́ ògiri kọ̀ọ̀kan àwọn àtẹ́rígbà náà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.