Eksodu 35:4-9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ohun èlò fun Àgọ́
4 (A)Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: 5 Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti:
“wúrà, fàdákà àti idẹ;
6 aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára;
àti irun ewúrẹ́;
7 awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù;
odò igi kasia;
8 òróró olifi fún títan iná;
olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;
9 òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.