Eksodu 20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Òfin mẹ́wàá
20 Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:
2 (A)“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.
3 (B)“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
4 (C)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 5 (D)Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. 6 Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
7 (E)Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.
8 (F)Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́. 9 Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, 10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ. 11 Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.
12 (G)(H) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
13 (I)(J) Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.
14 (K)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
15 (L)Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
16 (M)Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
17 (N)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”
18 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19 Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnrarẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”
20 Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”
21 Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.
22 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli: ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnrayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. 23 (O)Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.
24 (P)“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀. 25 (Q)Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́. 26 Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.