Efesu 6:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra.
Read full chapter
Matiu 25:1-13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Òwe àwọn wúńdíá mẹ́wàá
25 (A)“Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó. 2 Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n. 3 Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́. 4 Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn. 5 Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.
6 “Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’
7 “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe. 8 Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí fìtílà wọn ń kú lọ.
9 “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba à ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.
10 (B)“Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àsè ìgbéyàwó, lẹ́yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.
11 (C)“Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’
12 “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’
13 (D)“Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ Ènìyàn yóò dé.
Read full chapter
Marku 13:33-37
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
33 (A)Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé. 34 (B)Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà rere: Ẹni tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi àṣẹ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe, ó sì fi àṣẹ fún ẹni tó dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà.
35 (C)“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀. 36 Àti wí pé nígbà tí ó bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun. 37 Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí fun gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.