Òwe 28
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
28 Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e
ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.
2 Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀,
ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.
3 Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára
dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.
4 Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú
ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
5 Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi
ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.
6 Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù
ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.
7 Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.
8 Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù
ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.
9 Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,
kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
10 Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú
yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀
ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
11 Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
12 Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta;
ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.
13 Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
14 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo
ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.
15 Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀
ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.
16 Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú,
ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mún ọjọ́ rẹ̀ pẹ́.
17 Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn
yóò máa joró rẹ̀ títí ikú
má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
18 Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là,
ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.
19 Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.
20 Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an
ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.
21 Ojúsàájú ṣíṣe kò dára,
síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
22 Ahun ń sáré àti là
kò sì funra pé òsì dúró de òun.
23 Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn
ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
24 Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè
tí ó sì wí pé “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”
irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.
25 Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.
26 Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n
ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.
27 Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
28 Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora;
ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé,
àwọn olódodo ń gbilẹ̀ sí i.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.