Esteri 9:12-14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”
13 Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”
14 Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.