Orin Solomoni 5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Olólùfẹ́
5 Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.
Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;
mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.
Ọ̀rẹ́
Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,
àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.
Olùfẹ́
2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.
Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.
“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,
àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi
Orí mi kún fún omi ìrì,
irun mi kún fún òtútù òru.”
3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?
Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?
4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn
inú mi sì yọ́ sí i
5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,
òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn
sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn
6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ
ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.
Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.
Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn
7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.
Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;
wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!
8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín
bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,
kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?
Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
Ọ̀rẹ́
9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ
tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?
Olùfẹ́
10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n
ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.
11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ
ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ
ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò
12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà
ní ẹ̀bá odò tí ń sàn,
tí a fi wàrà wẹ̀,
tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́
13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí
tí ó sun òórùn tùràrí dídùn
Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì
ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn
14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,
tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká
Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán
tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mábù
tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára
Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,
tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.
16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀
ó wu ni pátápátá.
Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.