Malaki 2:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhu ìwà àrékérekè olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀?
Read full chapter
Efesu 4:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.
Read full chapter
Romu 11:36
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
36 (A)Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;
ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.
1 Kọrinti 1:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà.
Read full chapter
Efesu 4:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan.
Read full chapter
Johanu 1:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.
Read full chapter
Kolose 1:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.