Luku 7:13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 (A)Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”
Read full chapter
Luku 3:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
Read full chapter
Eksodu 22:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìdáàbòbò ohun ìní
22 “Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí.
Read full chapter
Lefitiku 6:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.
Read full chapter
Numeri 5:6-7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi. 7 Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.