Isaiah 40:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
lọ sí orí òkè gíga.
Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
sọ fún àwọn ìlú u Juda,
“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
Isaiah 52:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè
ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá,
tí wọ́n kéde àlàáfíà,
tí ó mú ìhìnrere wá,
tí ó kéde ìgbàlà,
tí ó sọ fún Sioni pé,
“Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”
Ìṣe àwọn Aposteli 10:36
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
36 Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo
Read full chapter
Romu 10:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 (A)Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.