Daniẹli 4:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ ààmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn.
Read full chapter
Marku 13:22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
22 (A)Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 2:19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
19 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,
àti àwọn ààmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;
ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;
Ìṣe àwọn Aposteli 4:30
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
30 Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”
Read full chapter
Romu 15:19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
19 (A)nípa agbára iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìhìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Read full chapter
Heberu 2:4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.