Saamu 110
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ti Dafidi. Saamu.
110 (A)Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
4 (B)Olúwa ti búra,
kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.